Numbers 11:27-29

27Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.”

28Joṣua ọmọ Nuni tí í ṣe ìránṣẹ́ Mose, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mose olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!”

29Mose sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa sì fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!”
Copyright information for YorBMYO